69:1
Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!
69:2
Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
69:3
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
69:4
Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.[1]
69:5
Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
69:6
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
69:7
Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.[1]
69:8
Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?
69:9
Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.
69:10
Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.
69:11
Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.
69:12
Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.
69:13
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,
69:14
tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,
69:15
ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.
69:16
Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.
69:17
Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.
69:18
Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).
69:19
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.
69:20
Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.”
69:21
Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí
69:22
nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
69:23
Àwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó.
69:24
Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.
69:25
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi![1]
69:26
Àti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.
69:27
Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).
69:28
Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.
69:29
Agbára mi sì ti parun.”
69:30
Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.
69:31
Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.
69:32
Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u[1] ni kí ẹ kì í sí.
69:33
Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.
69:34
Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
69:35
Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.
69:36
Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.
69:37
Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
69:38
Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra
69:39
àti ohun tí ẹ ò fojú rí.
69:40
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.[1]
69:41
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
69:42
Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
69:43
Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
69:44
Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
69:45
Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
69:46
Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
69:47
Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
69:48
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
69:49
Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.
69:50
Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.
69:51
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.
69:52
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.