91:1
                                        
                                    
                                    Allāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:2
                                        
                                    
                                    Ó tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:3
                                        
                                    
                                    Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:4
                                        
                                    
                                    Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:5
                                        
                                    
                                    Ó tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n[1] búra?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:6
                                        
                                    
                                    Ó tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:7
                                        
                                    
                                    Ó tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:8
                                        
                                    
                                    Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:9
                                        
                                    
                                    Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:10
                                        
                                    
                                    Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:11
                                        
                                    
                                    Ìjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:12
                                        
                                    
                                    (Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:13
                                        
                                    
                                    Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).”
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:14
                                        
                                    
                                    Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            91:15
                                        
                                    
                                    (Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.