54:1
                                        
                                    
                                    Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:2
                                        
                                    
                                    Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: “Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí).”[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:3
                                        
                                    
                                    Wọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn. [1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:4
                                        
                                    
                                    Dájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú[1] wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:5
                                        
                                    
                                    (al-Ƙur’ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:6
                                        
                                    
                                    Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:7
                                        
                                    
                                    Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:8
                                        
                                    
                                    Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Èyí ni ọjọ́ ìṣòro.”
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:9
                                        
                                    
                                    Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:10
                                        
                                    
                                    Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.”
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:11
                                        
                                    
                                    Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:12
                                        
                                    
                                    A tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:13
                                        
                                    
                                    A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:14
                                        
                                    
                                    tí ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:15
                                        
                                    
                                    Dájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:16
                                        
                                    
                                    Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:17
                                        
                                    
                                    Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:18
                                        
                                    
                                    Ìran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:19
                                        
                                    
                                    Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:20
                                        
                                    
                                    Ó ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:21
                                        
                                    
                                    Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:22
                                        
                                    
                                    Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:23
                                        
                                    
                                    Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:24
                                        
                                    
                                    Wọ́n wí pé: “Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:25
                                        
                                    
                                    Ṣé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni.”
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:26
                                        
                                    
                                    Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:27
                                        
                                    
                                    Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:28
                                        
                                    
                                    Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:29
                                        
                                    
                                    Wọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:30
                                        
                                    
                                    Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:31
                                        
                                    
                                    Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:32
                                        
                                    
                                    Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:33
                                        
                                    
                                    Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:34
                                        
                                    
                                    Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:35
                                        
                                    
                                    (Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa).
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:36
                                        
                                    
                                    Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:37
                                        
                                    
                                    Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:38
                                        
                                    
                                    Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:39
                                        
                                    
                                    Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:40
                                        
                                    
                                    Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:41
                                        
                                    
                                    Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:42
                                        
                                    
                                    Wọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú).
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:43
                                        
                                    
                                    Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:44
                                        
                                    
                                    Tàbí wọ́n ń wí pé: “Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)”
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:45
                                        
                                    
                                    A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:46
                                        
                                    
                                    Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:47
                                        
                                    
                                    Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:48
                                        
                                    
                                    Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:49
                                        
                                    
                                    Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:50
                                        
                                    
                                    Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.[1]
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:51
                                        
                                    
                                    Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:52
                                        
                                    
                                    Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:53
                                        
                                    
                                    Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:54
                                        
                                    
                                    Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
                                
                                
                        
                                    
                                        
                                            54:55
                                        
                                    
                                    Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.